Home / Business / Yoruba Poem – Ore Lope Ika Ko Sunwon

Yoruba Poem – Ore Lope Ika Ko Sunwon

Gbogbo e da yowu to kundun ika,ko ma ranti ojo esan. Gbogbo irufe eda tin so ogulutu ki won o ma reti idaro laipe ojo, nitoripe ohun aba f’onika la o fisan. Idaro gba koko ni idaro gba’de.

Oni bara kan feran lati maa toro baara loja oba ni ilu kan ti ako ni menu ba. O gbajumo pupo, teru-tomo lo feran lati ma bun-un lowo. Oni toro n fun ni tooro, oni kobo naa n s’aa biipa won semo. Bowo eku se mo saa nii se fi nu’ju. Kowa si bi iye owo ti won bun-un se le poto, oro kan soso naa ni o tenu mo, yi o wipe”arayin le sefun”. Kaefi ni oro naa je fun awon eniyan pe iru eda woni eleyi. Awon kan ti wipe iso ni olokunrun re fi n dupe.

Ni irole ojo kan,oni baara yii ko duro loja oba . O yiilu po lojo naa ni,O gba iwaju ile “LAMORIN” koja,lamorin fun lowo. O rin titi,o d’ogude “TAMEDO”tamedo gbe akara oni majele le lowo,o dupe gege bi ise re”arayin le sefun”. Ebi ko se bee pa lojo naa, o toju akara na sinu apo owo re osi ba tire lo .

Ko rin ju iwon isoko kan lo t’ofi kan ibogi loba ni k’oun o sinmi die.kope pupo ni omodomodebinrin kan n sunnkun koja,ojo ori re kole ju odun marun lo. Oni baara yii pe,o biile re ohun to gb’omije loju re.o ko ,o ro fun pe ebi lo n se be naa oun ni pasan. Ko salaitu’su de isale ikoko pe omo ile iwe ni oun ati pe oun dari lole ni.

Aanu se oni baara yii,o bi odomodebinrin naa boya o le ba oun fi ife je akara t’oun ni dani. Eye ko soka lo fi dahun pe oun niife si.o gba akara naa osi dupe lowo oni baara.osi ba tire lo.

Ajerin ni odomodebinrin yii n je akara na lo. O ku die ko wole,o yara ju yinkinni t’o ku e nu. Leyin iseju meedogun to wole lo gbawo mo’nu.

Tosi n ke’rora inu rirun.o ku die kemi o bo lenu re ni “TAMEDO”tin se baba re wole,o bi lere oun t’oje(eat) k’oro o to da boti da. Odomodebinrin yii yannana oro, o je koye baba re pe oni baara kan lofi akara saanu oun nigba ti ebi n pa sannaba s’oun lara….,’Mo gbe o o,omo yii ti pami o,’tamedo wi.

O gbe omo yii jannajanna jade boye o le doola emi re, sungbon aso kob’omoye mo. Omoye ti rin’hoho wo’ja.kato seju pe, ogunna kan soso re bo s’omi.(Omo re kan soso naa ku)Ebu ika.

Ika kope ara mi. Ore lope.

Source & written By: Raymond Agbaje

About admin

Check Also

Untold Story Of The Legendary Alabukun Powder And Its Maker

Jacob Sogboyega Odulate, the Blessed Jacob, sat at the work table in his laboratory, writing …