Ẹni a ni kofẹ ni loju, ata lofi sẹnu
Eyi tani ko kinni lẹyin, ẹgun niyẹn fi sọwọ
Eyi aba fọrọ lọ, alaroka pọnbele ni
Igi da ẹyẹ fo, lọrọ ọmọ araaye
Adaba wọn o nani aun kungbẹ, Ina njo ẹyẹ wọn nlọ ni
Bi adaba awọn ọta ba n pegede, jẹ ki ẹyẹlẹ ti ẹ ma woye ni o
Awọn agba bọ, wọn ni ” aroye niṣẹ ibaka nigbo, igbe kike lasan ni iṣẹ ẹyẹ loko ”
Orofo fi gbogbo ọjọ aye ti ẹ rojọ, Awoko fi ti ẹ kọrin
Aiyekootọ to tun fi igba gbogbo fọhunrere seti ọmọ araye
Sibẹsibẹ aye tun da ọmọ ẹyẹ loro
Awọn amoye sọ wipe ” kilode ti araaye o fẹran ki wọn ṣe ọmọ ẹyẹ loore ”
Ọrẹ wa kan ni ” ṣebi oore ọhun ni Igun ṣe, ti igun fi pa lori
Oore l’akalamagbo na ṣe to fi yọ gẹgẹ lọrun ”
Bi wọn ṣe nyi ẹ ṣebe, loun yi wọn si pooro
O si bawọn gbagbọ wipe aparo kan o gaju kan lọ
Iwo toun wo aparo, bi ko fi dala ni
Aṣa o fẹ k’oromọdiyẹ o dagba
Awodi oke rẹ o si mọ wipe ara ilẹ nwo ohun
Aṣa nke koowe nke, Aṣa o mọ wipe koowe fẹ pa hun lọmọ jẹ ni
O wa ndasa ” bo ba kọwọ kan adan, adan o fi rọgi ”
E̩lulu toun fa ojo lọrọ rẹ, Ori ara ẹ ni o fa le.
Source from: Proudly Yorùbá. Lati ọwọ: Raymond Ajeigbe