Obinrin ni aya okunrin, Obinrin ni iya okunrin
Okunrin a ma lagbara sugbon obinrin a ma l’ete
Ete si niyi, ni iwon ju agbara lo
Ni won ma fi ni wipe Okunrin ti obinrin o le mu, iyen ti mi tan l’atano
Obinrin a pa eje modi, atun fidi le le, Okunrin to t’eje lese lojo si nkan? o fin tiro rin ni.
Obinrin a bi omu rigbinrigbin laya, abidi yanyan
Okunrin ti ofi oju kan omu obinrin, ara e aji pepe, imo atoye ara mo leran
Bebe idi obinrin a ma gbeleke duro, won atun ma fi pon omo ye.
Bi Okunrin o ni Obinrin n’ile a ma kanra
Ogbeni ti o ba Obinrin lopo to wa si labara, on bo wa bebe bodo la
Yoruba ni awari ni Obinrin nwa nkan obe, bi ile ba tinmo, koto dale, Obinrin a ti ika bomo lenu.
Bi Okunrin mi ba soro, a fibi ojo nkun ni, bi Obinrin ba soro, a ma dun leti bi ti eye Awoko
Bi Obinrin ba loyun, won a ma ki pe eku Ikunra
Bi Obinrin bi omo, won a ki pe eku ewu omo
Bi Obinrin ba wa fi oju kan ela, araye won a bun laso
Bi Obinrin n’ife Okunrin kan, a di alomoko
Obinrin won a ma di abarameje, won a di Iya agba. won a fi daa bobo ile.
Bi Obinrin ba l’eye to n ro dede lode orun, awon omo araye won ma ki ni Olokiki oru.
Ohun Obinrin fi se abe, kosi ohun to dun to
Lodifa fun Adigun oko Abebi, ti babalawo ni ko lowa ohun to dun ju Obinrin lo, ojehun de oke Ido, Mewon ati ipatele oke.
Nigba to dari wole, okan lu abebi, opada loba babalawo pe, baba mode oke Ido,
Mewon ati ipatele oke mo jeun kiri, onje won dun yungba sugbon nigba timo dele, kini ara Abebi, baba, kosi ohun to dun to
Written By: Bola Olalekan