~Iwonran olokun, abara le kokooko bi ota,
~Difa fun Ori Apere
~Omo atakara sola
~Nje ibi ori gbe ni owo
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Nibi ori gbe ko’le
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Nibi ori gbe nni ire gbogbo
~Akara, Ori je won o ka mi mon won, Akara!
~Ori apeere, ori apesin,
~Iwa ni finin joye, Ori ni finin joba,
~Ori ni bani rogun tafi nsegun,
~Aba fi orisa sile, Ori lababo,
~Ojo Ori ngbeni nibo ni orisa wa,
~Eni Ori ba base ni taja, ni jere, ni kere oja dele,
~Nba tete mon pe Ori ni uba tima saagun,
~Ase ori eni ni gbe ni,
~Oogun lolojo kan iponju, Ori lolojo gbogbo,
~Ori agbe logbe pade alaro,
~Ori aluko logbe pade olosun,
~Ori lekeleke logbe pade elefun.
~Ori mi gbemi pade ire.
~Ibi oju ibi, base bi eru labi Omo-oba,
~Ori tiwon gbe waye lotooto,
~Sebi ojo toro si ewuro loro si ireke,
~Ohun gbogbo lowo Ori,
~Ori logbe aje fun olokun,
~Ori logbe iyo fun olosa,
~Ori latonan eni wasaye,
~Ba bimon tuntun amun Ori waye,
~Aba bo egun ile, k’abo orisa oja, afi k’abo ori eni,
~Bi aba ra fila etu, ta sin ade ide, Ori laafi de,
~Ori ni baba ara,
~Isebo ni isogun, ba se waye pe aori laari,
~Ohun gbogbo lowo Ori,
~Ori leja fi nlabu, Ori lemon fi nla opo,
~Eye onifo ko fi Ori sogi, Sebi Ori ni,
~Ori leleda eni, Ori lalabaro eni,
~Ori mi jafun mi, eleda mi gbeminija,
~Apari inun mi mon ba tode je
~Iwa mi maje kori ta ko mi
~Eleda mi ma sun
~Ori adiye oniburu koye dudu
~Ori lafi umun eran lawo
~Oojo layan ipin, ojo kan layan Ori
~Akunleyan, akunlegba ati ayanmo
~Akunleyan lohun ta yan pe afe je l’aye
~Akunlegba lonan ta yan pe aofi je ohun tafe je laye
~Ayanmo lohun ti ayan ti o se yi pada
~Ayanmo o gbo oogun, ori lelejo
~Ori koni ohun ogbe ni, amon apari inun(Iwa) uko?
~Ibi kan soso ni ‘Oriseki’ ‘Liemere’ ati ‘Afuwape’ ti yan ori
~Amon apari inun Afuwape gbe e
~Loba dara fun ju gbogbo won lo
~Ni won bani ‘awon omon ibi Afuwape gbe yan ori awon oba lo yan tawon’
~Afuwape ni ‘ibi kan lagbe yan ori, kadara o papo ni’
~Ori mi gbe ki nlowo
~Eleda mi lami kin lola
~Ori mi gbe mi
~Ori mi la mi
~Gbemi atete niran
~Gbemi atete gbeni ku foosa
~Ori nii gbe ni
~Ajawo, kii se oosa.
~Ori wo ibi ire ki o gbe mi de
~Ese wo ibi ire ki o sin mi re
~Ibi ope agunka ngbe mii re
~Emi ko mo ibe
~Difa fun Sasore
~Eyi to ji ni Kutukutu owuro
~Nje ti o ba tun ku ibi to dara ju eyi lo
~Ori mi ma sai gbe mi de ibe.
~Ori se mi lolowo, eleda mi semi l’olola
~Ori mase mi lerun, eleda mi mase mi ni iwofa
~Ori mi jafunmi, elada mi masun
~Ori mi ma gbagbe mi, elada mi magbabode
~Ire ni moyan nile Ajala-mopin, nibi kaluku ti yan ori
~Adeda, aseda, iba re Olodumare.
Ire oooooo!
Source & Written By: Samuel Olanrewaju Bill STAR