Bi a ba r’enikan t’o ja fafa, Yoruba maa nso pe ori e pe bi ori Alajo Somolu to ta moto ra keke, to gba ajo l’owo eédegbeta eniyan lai wo iwe, o da owo onikaluku pada lai si ariyan jiyan kankan. Ta a ni Alajo Somolu gan?
Sasa enìyàn lo mo pe, eeyan gidi ni Alajo Somolu ti won maa ns’oro e yi, kii se eni inu itan aroso rara.
Ni odun 1915, ni Isonyin Ijebu, obinrin kan bi ibeta ni asiko to je pe nkan iberu ati kayefì ni ki eeyan bi ju omo kan lo. Nitori asa ìgbaanì, aaye ni won sin Eta-oko, won fi se etutu ki awon alale o le f’iyedenu. Ko pe si asiko yi naa ti Kehinde lo ra aso wa, o ku Taiwo nikan s’aye.
Oju Taiwo ri eelaafi. Odomode owa ti baba re fi íle bora bi aso. Nigba ti ko si ona lati ka iwe jinna, Taiwo fi Isonyin Ijebu sile, o wa ise aje lo si Eko Akete. O fi ara re si ekose aranso nigba to de Eko. Taiwo kose o mo’se, ko na ina apa, otuwo jo, o ra oko akero. Laipe, o fi oko wiwa sile o bere esusu tabi ajo ojumo. Taiwo ta oko akero yi, o ra keke ologeere nitori keke lo le maa gbe lo si gbogbo ibi ti awon oloja to nsan esusu wa.
Ki ni Taiwo ro de ibi ajo gbigba? Awon ile ifowopamo to wa l’asiko yi ò ri ti awon iyaloja ati babaloja gbo, awon ile ise nla nla ni onibarawon.
Taiwo bere sii gba esuntere owo ajo ojumo l’owo awon mekunnu oloja, o nko fun won kiti n’íparí osù. O nya won l’owo lai gba dukia kankan fun iduro.
Bi ere bi ere, okowo esusu yi ngbile, bee ni oja awon onibara re naa ngberu si. Taiwo di ayanfe gbogbo oloja, o di ilumoka alajo ojumo. Ibi ti ounti a mo si Ile ifowopamo Mekunnu l’oni ti bere ni yen.
Awon agbegbe tó jé aresepa fun Taiwo ni Sangross, Baba Oloosa, Ojuwoye, Awolowo, Oyingbo, Olaleye ati Somolu,gbogbo oja ati agbegbe ti a daruko yi ni Taiwo ti ngba àjo. Awon onibara re feran rewon si f’inu tan tori won ò ri ki Taiwo ó fi dudu pe funfun fun won.
Alakori kii s’egbe alakowe nigba naa. Ko si ero isiro ti a mo si calculator, sugbon ori Taiwo pe, o ns’ise bi aago ni. Lai wo iwe akosíle, Taiwo a ma a so iye ti enikookan ti da si òun lowo.
Bi enikeni sì ba Taiwo jiyan, nigba ti won ba jo gbe gege le isiro, won a gba fun Taiwo kehin naa ni tori bo ba se wi pe o ri naa ni won ó ba a.
Gbogbo awon onibara re lo feki omo won o ni ori pipe bii Taiwo, won a si maa fi se akawe pe, ‘Ori omo mi pe bi ti Baba Alajo Somolu”,
Itan baba Alajo Somolu yi fi han wa bi aye se dara to ni asiko yen, kò si jìbìtì. Se awon eniyan kó ni won da ile ifowopamo sile ti won so ara won di eku òfónòn si wa l’orun, awon èèkàn inu ijo Olorun ti Oniwaasu nwarí fun? Taiwo fi igboya, oyaya, ati otito inu se ise re lai ri awokose kankan, o si di nkan pataki ninu itan ile Yoruba ti a nfi oruko rè suref’omo eni.
Ninu ikoko dudu l’eko funfun ti njade. Baba Alajo Somolu wo sakun oro, o woye nkan ti awon arailu nilò, lai ri iranlowo ijoba tabi ti olowo kan, o pakiti mole, pelu ifojúsùn ati èero pe atelewo eni kii tan’ni í je, o tiipa bee gba aimoye idile l’owo ebi ati ìse, o gba mekunnu l’owo awon agbalowomeerí ileifowópamo, ó ti ipa béè di olokiki eniyan titi ti oro re fi di àsà ti a ndá.
Taiwo Olunaike fi oruko to dara silè de omo ati aramodomo re.
Titi aye, ti asa ati ede Yoruba ba si nwa, a o ni ye so fun eni ti ori è pé wipé “Ori è pe bi ori Alajo Somolu”.
Source From: Proudly Yorùbá